Friday, December 1, 2023
MARKET UPDATE
Advertisement

TheCable

Ǹjẹ́ kí ènìyàn gbé àtọ̀ mì lè dín wàhálà àti iporuru/aisedede ọkàn kù?

Ǹjẹ́ kí ènìyàn gbé àtọ̀ mì lè dín wàhálà àti iporuru/aisedede ọkàn kù?
October 03
17:54 2022

Olùmúlò ìkànnì abẹ́yẹfò – Twitter kan ló sọ pé kí ènìyàn máa gbé àtọ̀ mì lè jẹ́ kí ó sùn dáadáa, din wàhálà àti aisedede/piporuru ọkàn kù. 

“Gbígbé àtọ̀ mì lè ṣe ìrànwọ́ fún ènìyàn tó bá ní irẹwẹsi ọkàn tàbí tí ó wà nínú ìbànújẹ, kí ènìyàn gbé àtọ̀ mì lè dín ìjayà kù, ó sì lè jẹ kí ènìyàn lè sún dáadáa,” atẹjade náà ló sọ báyìí.

Àwọn olùmúlò ojú òpó bù ọwọ ìfẹ́ lú àtẹ̀jáde náà ni ọ̀nà ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ lé ní ẹẹdẹgbẹta, wọn sì ti ṣe àtunpin atẹjade náà ni ọ̀nà ẹgbẹ̀rún mẹ́rin lé ní ọ́ọ̀dúnrún.

Wọn ṣ’atunpin àtẹ̀jáde yìí sì ojú òpó ìgbàlódé ibaraẹnidọrẹ – Facebook.

Advertisement

Àtọ̀, èyí tí a tún mọ̀ sì omi ara màá ń jáde láti nkan ọmọkùnrin ní àsìkò ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin. Ó ní àwọn sẹẹli tí ó lè sọ ẹyin obìnrin di ọmọ.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èròjà ló wà nínú àtọ̀, ara wọn ni fáítámì C àti àwọn akẹgbẹ rẹ bíi: ascorbic acid, calcium, citric acid, fructose, lactic acid, magnesium, zinc, potassium, sodium, fat, ati awọn eroja amúaradágbà.

KÍNI ÌWÁDÌÍ WÍ?

Biotilẹjẹpe kò tíì sí ìwádìí tó jinlẹ l’órí àǹfààní tí gbígbé àtọ̀ mì lè ṣe fún agọ ara ènìyàn, oríṣiríṣi àtẹ̀jáde nípa kókó ọ̀rọ̀ náà ló wà lórí ayélujára.

Advertisement

Púpọ̀ nínú àwọn ànfààní ki ènìyàn gbé àtọ̀ mì ló sopọ̀mọ́ awọn ìwádìí lórí èròjà inú àtọ̀ àti oun tí àwọn èròjà yìí ń ṣe ní agọ ara ènìyàn.

Ayẹwo ìwé ìròyìn TheCable fihàn pé ìwádìí tí wọ́n màá ń sáábà fi ti àhesọ náà lẹ́yìn ni èyí tí wọn gbé jáde ní ọdún 2002, inú èyí tí a ti lo àwọn obìnrin ọọdunrun dín ní méje fún àyẹ̀wò yìí. Ìwádìí náà fihàn pé irẹwẹsi ọkàn kò wọ́pọ̀ nínú àwọn obìnrin tó ń ní ajọsepọ pẹ̀lú ọkùnrin.

Ṣùgbọ́n, àwọn tó ṣe ìwádìí náà, tí kò mẹ́nuba gbígbé àtọ̀ mì, sọ pé èsì ìwádìí náà jẹ́ “àkọ́kọ́se, ó sì jẹ́ àbá lásán.”

Ìwádìí míràn tí wọn màá ń sáábà tọ́ka sí ni èyí tí wọn gbé jáde ní ọdún 2015 tí ó sọ wí pé àtọ̀ ní èròjà melatonin tí ó máa ń jẹ́ kí ènìyàn sùn. Ìwádìí yìí sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ tí melatonin ń ṣe fún nkan ọmọkùnrin. Ìwádìí náà ò fìgbà kankan mẹ́nuba oun tí yóò ṣẹlẹ̀ tí ènìyàn bá gbé àtọ̀ mì.

Advertisement

KÍNNI ÀWỌN AMÒYE SỌ NÍPA Ọ̀RỌ̀ YÌÍ?

TheCable kàn sí àwọn onímọ̀ nípa iṣẹ́ òògùn òyìnbó láti mọ bóyá òtítọ́ ni wí pé ìmọ̀ sayẹnsi ṣe àtìlẹ́yìn ahesọ yìí.

Advertisement

Ọjọgbọn Best Ordinioha, tí ó jẹ́ onímọ̀ nípa ẹ̀ka tó ń ṣe ìtọ́jú ìlera ọpọ ènìyàn láwùjọ sọ pé irọ́ ni àhesọ pé gbígbé àtọ̀ mì ń ṣe ànfààní fún agọ ara.

“Ti ànfààní kankan bá wà, a jẹ́ láti ìbálòpọ̀ kìíse nípasẹ̀ gbígbé àtọ̀ mì. Lòtítọ́ ní wí pé èròjà tí ń ṣe ara lóore wà nínú àtọ̀. Ṣùgbọ́n, àwọn èròjà yìí máa ń ṣe iranlọwọ fún okùnrin láti sọ ẹyin obìnrin di ọmọ. Kìíse pé kí wọn gbée mì, èròjà díẹ̀ ni à ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀”, ọjọgbọn náà ló sọ báyìí.

Advertisement

“Ó fẹ́ dàbí pé ẹni tó fi àtẹ̀jáde náà síta fẹ́ fi ṣe oun ìwúrí fún àwọn ènìyàn láti máa gbé àtọ̀ mì lásán ni, gẹ́gẹ́bí ẹ ti mọ̀ wí pé àwọn ẹlòmíràn kò ní fẹ́ ṣe irú nkan bẹ́ẹ̀. Tí a bá wo ọpọlọpọ nínú àwọn àhesọ tí wọn màa ń gbé káàkiri yìí, a gbọ́dọ̀ mọ ìdí tí onítọ̀ún fi sọ ǹkan yìí.”

Ayọ Ajeigbe, onímọ̀ nípa iṣẹ́ ọkàn sọ pé irọ́ ni àwọn àhesọ wọ̀nyí àti wí pé kò sí ìwádìí kan pàtó tó ṣe àtìlẹ́yìn àhesọ náà.

Advertisement

“Irọ ni ọpọlọpọ àwọn ahesọ yí nítorí pé àwọn ènìyàn kàn máa ń so àwọn ọ̀rọ̀ pọ ni. Biotilẹjẹpe èròjà melatonin wà nínú àtọ̀, èyí kò túmọ̀ sí pé ó ní ànfààní kankan fún agọ ara tí ènìyàn bá gbemì”, Ajeigbe ló sọ báyìí.

“Kò sí ìwádìí tó ṣe àtìlẹ́yìn àhesọ yìí, tí ó bá jẹ́ òtítọ́, yóò jẹ́ ọ̀nà àbáyọ fún ọpọlọpọ ènìyàn tó ní àwọn ìṣòro wọ̀nyí. Kódà, wọn á ti ṣe ìpèsè oògùn ti àtọ̀ wà nínú rẹ̀, ki àwọn ènìyàn lè lòó.”

Onímọ̀ nípa iṣẹ́ ọkàn náà fi kún-un wí pé ọpọlọpọ nínú àwọn ìwádìí tó ṣe àtìlẹ́yìn àhesọ náà kò ní olùkópa pupọ, èyí tí kò jẹ́ kí ìwádìí náà kún ojú òṣùwọ̀n. Ó tún fi kún-un pé àtọ̀ tó bá jáde láti nkan ọmọkùnrin kéré gan fún èròjà tó tibẹ wá láti ní ipa tó dájú lára ènìyàn tí wọn bá gbemì.

ÀBÁJÁDE ÌWÁDÌÍ 

Kòsí ẹ̀rí tó dájú pé gbígbé àtọ̀ mì lè jẹ́ kí ènìyàn lè sùn dáadáa, dín ibanujẹ/ijaya àti wàhálà kù. Ìmọ̀ sayẹnsi kò ṣe àtìlẹ́yìn fún àhesọ yìí.

Click on the link below to join TheCable Channel on WhatsApp for your Breaking News, Business Analysis, Politics, Fact Check, Sports and Entertainment News!

Tags

0 Comments

No Comments Yet!

There are no comments at the moment, do you want to add one?

Write a comment

Write a Comment

error: Content is protected from copying.