Sunday, December 3, 2023
MARKET UPDATE
Advertisement

TheCable

Ṣé òtítọ́ ni wí pé ìpínlẹ̀ Borno tóbi tó orílẹ̀-èdè UK àti Sweden?

Ṣé òtítọ́ ni wí pé ìpínlẹ̀ Borno tóbi tó orílẹ̀-èdè UK àti Sweden?
September 12
08:06 2022

Yemi Osinbajo, igbá-kejì Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sọ láìpẹ́ yìí pé, ìpínlẹ̀ Borno tóbi tó United Kingdom (UK) àti Sweden lápapọ̀ tàbí orílẹ̀-èdè UK àti Denmark. 

Nínú àtẹ̀jáde kan, Laolu Àkàndé, ẹni tí ó jẹ́ agbẹnusọ fún Osinbajo, fi ye wa pé igbá-kejì ààrẹ sọ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tí ó ń jíròrò pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé tí a ti ń kọ ni nípa ọrọ ajé ti ìlú Harvard (Harvard Business School) ní ìlú Amẹ́ríkà tó ṣe abẹwo síi ní Presidential villa, ibi ibùgbé ìjọba fún Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọjọ́ àìkú, ọjọ́ kejidinlọgbọn oṣù kẹjọ, ọdún yìí.

Ní ìgbà tí ó ń bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sọ̀rọ̀, Osinbajo ní kí àgbáyé lè ní òye bí ọrọ̀ ajé àti rògbòdìyàn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe tóbi tó pẹ̀lú bí ó ṣe takoko sí, o dáa kí a fi ye wọn.

“Lakọkọ, a ní láti mọriri bí Nàìjíríà ṣe tóbi tó, lára oun tí ó ṣe pàtàkì tí a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ ni àwọn iṣoro tí ó ń dojú kọ Nàìjíríà.

Advertisement

“Fún àpẹẹrẹ, ìpínlẹ̀ Borno tóbi tó orílẹ̀-èdè UK àti Sweden tabi orilẹ-èdè Denmark,” Ọjọgbọn nípa ofin náà ló sọ báyìí.

“Nítorí náà, tí ẹ bá gbọ́ ìròyìn nípa rògbòdìyàn ni Nàìjíríà, ó lè jẹ́ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé ní ibì kan, ó sì leè jẹ́ pé Ìpínlẹ̀ Èkó ati Abuja, olú ìlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nìkan ni àwọn ènìyàn ti gbọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí lori ayélujára, bẹẹni Nàìjíríà ṣe tóbi tó.

“Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ọrọ̀ ajé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ni ọ̀pọ̀ ìgbà, àwọn ènìyàn máa ń sábà fi bí ọrọ ajé àti rògbòdìyàn tí ó ṣẹlẹ̀ ni Naijiria ṣe tó wé ti àwọn orílẹ̀-èdè kékeré ní ilẹ̀ Áfíríkà, ṣùgbọ́n àpapọ̀ ọrọ̀ ajé (Gross Domestic Product) Ìpínlẹ̀ mẹ́wàá ni Naijiria tóbi ju ti àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí lọ.”

Advertisement

Ṣé ilẹ̀ tí ìpínlẹ̀ Borno ní ju ti UK àti Sweden lapapọ tàbí ti UK àti orílẹ̀-èdè Denmark?

Ọpọlọpọ ilé iṣẹ́ ìròyìn ló gbé ìròyìn yi.

Iṣaridaju

Advertisement

Ìwé Ìròyìn TheCable sàyẹ̀wò bí Ìpínlẹ̀ Borno ṣe tóbi tó, Ìpínlẹ̀ náà wà ní àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. A dá Ìpínlẹ̀ náà sílẹ̀ ní oṣù kejì, ọdún 1976, a yọ Ìpínlẹ̀ Yobe (dá sílẹ) láti ara Ìpínlẹ̀ Borno ní ọdún 1991.

A máa ń pe ìpínlẹ̀ Borno ni ilẹ̀ àlàáfíà, ní apá iwọoorun ìpínlẹ̀ Borno ni ìpínlẹ̀ Yobe wà. Borno ní ààlà pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Niger, Lake Chad àti Cameroon.

Ni orí ayélujára, ìjọba ìpínlẹ̀ Borno ṣàlàyé pé ìlú náà ní ilẹ̀ tí wiwọn rẹ tó ẹgbẹ̀rún ní ọna ọgọ́ta lé ní ọkan, le ni ẹgbẹ̀rún ati irínwó pẹ̀lú aarun dín ní ogójì (61,435sqkm), èyí tí ó fi jẹ́ ìpínlẹ̀ kejì tó tóbi jùlọ ní Nàìjíríà lẹ́yìn ìpínlẹ̀ Naija.

A ṣe ìmúlò data tí àjọ ètò ìṣirò-National Bureau of Statistics (NBS) gbé jáde ní ọdún 2020, a ríi wí pé gẹ́gẹ́bí data lati àjọ National Population Commission, èyí ni àjọ tí ó ń ṣètò ìkànìyàn ní ọdún 2019, iye ènìyàn tí ó ń gbé ní Ìpínlẹ̀ Borno jẹ́ mílíọ̀nù márùn pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún ní ọna ẹẹdẹgbẹrin (5.7 million).

Advertisement

Àwọn ìlú tí ó kórapọ tí ó ń jẹ UK ni England, Wales, Scotland àti Northern Ireland-àríwá orílẹ̀-èdè Republic of Ireland.

Data láti bánkì àpapọ̀ àgbáyé (World Bank) ni ọdún 2021 fihàn pé ilẹ̀ tí UK ní jẹ́ ọ̀kẹ́ méjìlá le ni ẹgbẹ̀rún ó dín ni àádọ́rin (241,930 km²).

Advertisement

Àjọ ètò ìṣirò orílẹ̀-èdè UK (UK’s Office of National Statistics), àjọ ètò ìṣirò tó tóbi jùlọ sọ wí pé iye ènìyàn orílẹ̀-èdè náà jẹ miliọnu mẹ́tadínníàádọ́rin (67 million).

Sweden wá ní ilẹ̀ Lárúbáwá tí agbegbe Scandinavia ni àríwá ilẹ̀ Yúrópù. Láti ọdún 1523 ni Olú ìlú orílẹ̀-èdè Sweden ti wà ní Stockholm. Ilẹ̀ tí Sweden wá ni ó pọju ní erékùṣù tí a mọ sí Scandinavia. Ilẹ̀ Sweden ni ààlà pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Norway.

Advertisement

Biotilẹjẹpe orílẹ̀-èdè náà tí wà láti bí ẹgbẹ̀rún ọdún, àyípadà ń dé bá ilẹ tí ó wà títí di bí ọdún 1809. Data Banki fún Àgbáyé (World Bank) fi ye wa pé ilẹ̀ tí orílẹ̀-èdè náà wà tó bí ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà irinwolenimeje àti ọdunrun lé ní mẹwa, ó sì ní iye ènìyàn tí ó jẹ miliọnu mẹwa àti ẹgbẹ̀rún ní ọna irinwo.

Denmark wa ní erékùṣù ìlú Jutland, tó ràn lọ sí iha àríwá láti àárín agbègbè ila oorun ti Yúrópù. Jutland gba méjì nínú idamẹta iwọn ilẹ̀ orílè-èdè naa.

Advertisement

Ní ọdún 2021, data banki agbaye fihàn pé iwọn ilẹ̀ ìlú Denmark jẹ ẹgbẹ̀rún ní ọna ogójì (40,000 km²), iye ènìyàn tó si n gbe ni orílẹ̀-èdè náà jẹ mílíọ̀nù márùn-ún lé ní ẹgbẹ̀rún ní ọna ẹgbẹrin (5.8m).

Ní òtítọ́ ni Borno ju ìlú Denmark lọ, ó sì fẹrẹ ní iye ènìyàn kan náà. Sùgbọ́n Ìpínlẹ̀ Borno kéré sí iwọn ilẹ̀ àti iye ènìyàn Sweden àti UK.

Ìwádìí TheCable fihàn pé ìwọn ilẹ̀ ati iye ènìyàn tó wà ni UK nikan ju ti ìpínlẹ̀ Borno lọ, laiti mẹnuba Sweden tàbí Denmark.

Borno United Kingdom  Sweden Denmark United Kingdom Sweden United Kingdom + Denmark
Landmass (km²) 61,435 241,930  407,310  40,000  649,240  281,930
Population 5,751,590 67,081,000 10,415,811 5,856,733 77,496,811 72,937,733

Àbájáde Ìwádìí 

Irọ́ àti àsọdùn ni ọ̀rọ̀ tí Osinbajo, igbá-kejì Ààrẹ orílè-èdè Nàìjíríà sọ pé ilẹ̀ Ìpínlẹ̀ Borno tóbi tó àpapọ̀ ilẹ̀ UK ati Sweden tàbí tí UK àti Denmark.

Click on the link below to join TheCable Channel on WhatsApp for your Breaking News, Business Analysis, Politics, Fact Check, Sports and Entertainment News!

Tags

0 Comments

No Comments Yet!

There are no comments at the moment, do you want to add one?

Write a comment

Write a Comment

error: Content is protected from copying.