Advertisement
Advertisement

Rárá, wọn kò tíì fi Woodberry sílẹ̀ ní ẹ̀wọ̀n

Atẹjade kan lórí àwọn ohun ibaraẹnise ìgbàlódé (social media) ti sọ pé wọ́n ti fi Olalekan Ponle, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn mọ̀ sí Woodberry sílẹ̀ ní ẹ̀wọ̀n.

Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá ló ti wòó/ríi ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn mẹ́tàláléníigba ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn mẹ́taléníọgọ́rin ló pín in ní orí ohun ìgbàlódé ibaraẹnise tí a mọ̀ sí X (tí à ń pè ní Twitter tẹ́lẹ̀).

TA NI WOODBERRY?

Woodberry jẹ́ ọmọ Naijiria tí ó jẹ́ ìlúmọ̀ọ́ọ́ká, ènìyàn pàtàkì orí ayélujára tí ó sì jẹ́ ọ̀rẹ́ Ramon Abbas, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn mọ̀ sí Hushpuppi, ẹni tí òhun náà jẹ́ ọmọ Nàìjíríà. Wọ́n fi Abbas sí ẹ̀wọ̀n nítorí ìwà àfọwọ́rá lórí ayélujára ni oṣù kọkànlá, ọdún 2022.

Ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù kẹfà, ọdún 2020, àwọn agbófinró Dubai ní orílẹ̀-èdè United Arab Emirates mú àwọn méjèèjì nítorí ìwà jìbìtì.

Advertisement

Wọ́n sì gbé wọn lọ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láti lè rí sí ọ̀rọ̀ yìí bí òfin ṣe wí.

Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Woodberry ni pé ó lu àwọn ènìyàn ní jìbìtì owó tí ó tó ẹgbẹ̀rún igba ó dín méjìlá dọ́là ($188,000). Ó lé ní ọdún méjì tí ó fi sọ pé òhun kò jẹ ẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òhun.

Àmọ́sá, ó yí ohùn padà, ó sì gbà pé òhun jẹ ẹ̀bi ẹ̀sùn kan tí ó jẹ́ jìbìtì orí ayélujára níbi ìgbẹ́jọ́ ṣemíjẹ́jẹ́ ní oṣù kẹrin, ọdún 2023 ni ilé ẹjọ́ tí a mọ̀ sí US District Court for Northern Illinois.

Robert Gettleman, adájọ́ gba ẹ̀bẹ̀ Woodberry nínú ẹjọ́ tí ó dá ní ọjọ́ kẹfà, ó sì ní ó jẹ ẹbí ẹ̀sùn mẹ́jọ tí wọ́n fi kàn án.

Advertisement

Ní ọjọ́ kọkànlá, oṣù keje, ọdún 2023, wọ́n fi Woodberry sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́jọ, wọ́n sì ní kó san mílíọ̀nù mẹ́jọ dọ́là ($8 million) padà fún àwọn méje lára àwọn tó lù ní jìbìtì fún àtúnṣe.

ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ

Advertisement

Láti lè mọ òtítọ́ nípa ọ̀rọ̀ yìí àti láti mọ ibi tí Woodberry wà, TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára yẹ ìwé tí orúkọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n wà nínú rẹ̀ wò tí ó jẹ́ ti Federal Bureau of Prisons.

A rí orúkọ, nọ́mbà aṣọ ọgbà ẹ̀wọ̀n, ọjọ́ orí, ọjọ́ tí wọ́n máa fiWoodberry sílẹ̀ àti ibi tí ó wà.

Advertisement

Àyẹ̀wò yìí fi hàn pé Fort Dix Federal Correctional Institution ló wà. Wọ́n máa fi sílẹ̀ ní oṣù kẹwàá, ọdún 2027. Ọdún méjì lẹhin èyí ni wọn yóò fi Hushpuppi sílẹ̀.

Advertisement

BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ 

Ọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn sọ pé wọn ti fi Woodberry sílẹ̀ ní ẹ̀wọ̀n kì í ṣe òótọ́.

Tí a bá wo ìwé US Federal Bureau of Prisons, arákùnrin yìí sì í ń ṣe ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́jọ tí wọn fún un lọ́wọ́.

 

Add a comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Click on the link below to join TheCable Channel on WhatsApp for your Breaking News, Business Analysis, Politics, Fact Check, Sports and Entertainment News!

error: Content is protected from copying.