Saturday, May 11, 2024
MARKET UPDATE
Advertisement Topt

TheCable

Ǹjẹ́ Shell fẹ́ dá iṣẹ́ wọn dúró ní Nàìjíríà?

Ǹjẹ́ Shell fẹ́ dá iṣẹ́ wọn dúró ní Nàìjíríà?
January 23
05:31 2024

Àwọn ènìyàn tí ń sọ ọ nínú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń pín kiri ní orí àwọn ohun ìbáraẹnise ìgbàlódé (social media) pé Shell, àwọn tí ó ń sisẹ epo rọ̀bì fẹ́ kúrò ní Nàìjíríà.

Àwọn ọmọ Nàìjíríà fèsì sí ọ̀rọ̀ Shell náà pẹ̀lú oríṣiríṣi ọ̀rọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èyí tí kìí ṣe òótọ.

Àwọn ọ̀rọ̀ yìí, èyí tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn, tí wọ́n sì pín ní orí ohun ìgbàlódé ìbáraẹnise alami Krọọsi (X, tí a mọ sì Twitter) tẹ́lẹ̀rí sọ pé Shell tí dá ọwọ́ iṣẹ́ dúró ní Nàìjíríà. Shell tí ń ṣe bisinẹẹsi (ọrọ̀ ajé) ní Nàìjíríà láti ọgọ́rin ọdún ó lé díẹ̀.

“Shell ṣẹ̀ṣẹ̀ kéde pé àwọn fẹ́ kúrò ní Nàìjíríà. Kí ni àwọn aláwọ̀ funfun yìí ń rí tí a kò rí” Olumulo kan tí a mọ̀ sí @Naija_Activist ló sọ bayii.

Advertisement

Olumulo míràn tí a mọ̀ sí @_pheranme sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà. Ó ní “Kí ló ń ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà?”

Olumulo orí ohun ìbáraẹnise alami Krọọsi kan tí a mọ̀ sí @ThisisNot1967_ sọ pé “Shell BP fẹ kúrò ní Nàìjíríà lẹhin ọdún marunlelọgọrin tí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ ní Nàìjíríà.”

Advertisement

IFIDIODODOMULẸ

Nígbà tí wọ́n ń ṣe ìfitónilétí nípa ayipada bí wọ́n ṣe ń ṣe bisinẹẹsi ní Nàìjíríà, Shell sọ pé nípa ìlànà òfin, àwọn máa ta Shell Petroleum Development Company of Nigeria Limited (SPDC).

Bisinẹẹsi yìí yóò di ti Renaissance, èyí tí ó jẹ́ ilé-iṣẹ́ kan tí  àwọn ilé-iṣẹ́ márùn-ún wà lábẹ́ rẹ̀.

Mẹrin nínú àwọn ilé-iṣẹ́ yìí ń ṣe iṣẹ́ epo rọ̀bì. Ìkan yòókù síi ń ṣe ohun tí ó jọ mọ́ọ. Àwọn mẹ́rin náà ni: ND Western, Aradel Energy, First Exploration and Production (First E&P), Waltersmith and Petrolin.

SDPC  ni ó ń ṣe àkóso NNPC/SPDC/TotalEnergies/NAOC joint venture, èyí tí Nigerian National Petroleum Company Limited (55 percent holding), SPDC (30 percent), TotalEnergies (10 percent) ati Nigerian Agip Oil Company Limited (5 pércent) wà lábẹ́ rẹ̀.

Nínú ọ̀rọ̀ tí Shell fi síta, wọ́n ní títa ìkan lára àwọn ẹ̀ka iṣẹ́ àwọn kò túmọ̀ sí pé àwọn fẹ́ kúrò ní Nàìjíríà. Wọ́n ní àwọn sì ní bisinẹẹsi mẹ́ta ní Nàìjíríà.

Àwọn bisinẹẹsi mẹ́ta náà ni Shell Nigeria Exploration and Production Company Limited (SNEPCo), Shell Nigeria Gas Limited (SNG) àti Daystar Power Group.

Ní àfikún, bí ìdá márùn-únlelogun nínú NLNG (Nigeria Liquefied Natural Gas) ni ó jẹ́ ti Shell. NLNG máa nta gaasi, èyí tí a máa ń rí nínú epo rọ̀bì sì òkè òkun.

SHELL SÌ Ń ṢE BISINẸẸSI NÍ NÀÌJÍRÍÀ

SNEPCo, èyí tí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ akitiyan gaasi fifọ ní ibi tí a mọ̀ sí Bonga ni Gulf of Guinea kò ní dá ọwọ́ iṣẹ́ dúró.

Daystar, èyí tí ó di ti Shell ní oṣù Kejìlá, ọdún 2022 sì máa máa ṣe bisinẹẹsi wọn ní Nàìjíríà.

SNG náà yóò sì máa ṣe bisinẹẹsi ní Nàìjíríà.

ÌDÍ TÍ SHELL ṢE DÁ LÁRA ÀWỌN BISINẸẸSI WỌN DÚRÓ NÍ NÀÌJÍRÍÀ

Àwọn ènìyàn mọ̀ pé Shell yóò tà lára àwọn bisinẹẹsi wọn nítorí epo rọ̀bì tí ó ń ṣòfò, eléyìí tí ó ń fa kí wọn máa na owo púpọ̀ láti ṣe àtúnṣe àti lórí ẹjọ́.

Pípè tí wọ́n pè wọ́n sí ilé ẹjọ́ ni kò jẹ́ kí Shell tá lára àwọn bisinẹẹsi wọn.

Ní oṣù kẹta, ọdún 2022, ilé ẹjọ́ kotẹmilọrun ní Owerri dá Shell dúró kí wọ́n má tá bisinẹẹsi tàbí ohun wọn kankan títí ilé ẹjọ́ tí ó gaju lọ yóò fi ṣe ìdájọ́.

Ní oṣù keje, ọdún 2022, Shell da iyọwọkuro nínú ara àwọn bisinẹẹsi yìí dúró di ìgbà tí èsì ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tí ó ga jù lọ yóò fi jáde.

ÀWỌN ILÉ-IṢẸ́ ÒKÈÈRÈ TÍ WỌ́N Ń TA NKAN WỌN

Àwọn ilé-iṣẹ́ òkèèrè kan náà tí ń tà nkan/bisinẹẹsi wọn.

Ní oṣù kejì, ọdún 2022, Seplat Energy Plc gbà láti ra ìpín iye nkan tí ExxonMobil ní nínú Mobil Producing Nigeria Unlimited (MPNU).

Àmọ́sá, lẹ́hìn ọdún kan, àjọṣepọ̀ yìí kò tíì ní ìyanjú nítorí wahala tí ó so mọ́ ifiofinde nkan.

Nínú oṣù kẹrin, ọdún 2022, TotalEnergies kéde àwọn ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe láti tá ìpín wọn nínú ajọni bisinẹẹsi epo rọ̀bì.

Ní oṣù kẹsàn-án, ọdún 2023, Oando sọ pé àwọn ti ti ọwọ́ bọ ìwé láti ra ìpín ọgọ́rùn-ún tí Eni ní ní Nigerian Agip Oil Company Limited (NAOC Ltd).

Equinor, bisinẹẹsi epo tí ó jẹ́ ti orílẹ̀-èdè Norwegia, nínú oṣù kọkànlá, ọdún 2023 sọ pé àwọn ti ta bisinẹẹsi wọn ní Nàìjíríà àti èyí tí wọ́n ní Agbami oil field, fún Chappal Energies, bisinẹẹsi tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Naijiria kan.

BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ

Ọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn ń sọ pé Shell fẹ́ kúrò ní Nàìjíríà kìí se òótọ́.

Ilé-iṣẹ́ yìí sì ní bisinẹẹsi mẹ́ta ní Nàìjíríà.

Click on the link below to join TheCable Channel on WhatsApp for your Breaking News, Business Analysis, Politics, Fact Check, Sports and Entertainment News!

Tags

0 Comments

No Comments Yet!

There are no comments at the moment, do you want to add one?

Write a comment

Write a Comment

error: Content is protected from copying.