Saturday, April 27, 2024
MARKET UPDATE
Advertisement Topt

TheCable

Advertisement lead

Ṣé Buhari yọ owó kiaramabani àwọn ènìyàn fún díṣù gẹ́gẹ́bí Garba Shehu ṣe wí?

Ṣé Buhari yọ owó kiaramabani àwọn ènìyàn fún díṣù gẹ́gẹ́bí Garba Shehu ṣe wí?
June 30
21:30 2023

Ní ọjọ́ Ajé, Garba Shehu, ẹni tí ó jẹ agbẹnusọ fún Ààrẹ Muhammadu Buhari, Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀rí sọ wí pé Buhari ni ó yọ owó kiaramabani àwọn ènìyàn fún díṣù (diesel subsidy).

Nígbà tí ó ń ṣàlàyé ìdí tí Ìjọba Buhari fi kùnà láti yọ owó kiaramabani àwọn ènìyàn fún díṣù (diesel subsidy), ó sọ pé Ààrẹ nígbàkanrí náà ṣe báyìí kí ẹgbẹ́ òsèlú All Progressives Congress (APC) má bàa fìdírẹmi nínú ìdìbò ọdún 2023.

Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ pé Buhari ti yọ àwọn owó kiaramabani àwọn ènìyàn ní pàtàkì jù lọ ti díṣù.

“Owó kiaramabani àwọn ènìyàn ti owo iná mọ̀nàmọ́ná pọ̀ gan-an. Owó jìbìtì kiaramabani àwọn ènìyàn tí orí ajílẹ̀, ti orí owó ìrìnàjò ilẹ̀ mímọ́ tí àwọn ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ àti àwọn Mùsùlùmí. Ṣé o rántí? owó iranlọwọ tí díṣù, tí epo ọkọ̀ Òfurufú àti ti epo kẹrosini,” ó wí báyìí.

Advertisement

“Ti gaasi ìdáná àti àwọn miran tí a bá ní a ṣètò dáadáa nípa wọn. Ǹjẹ́ o rántí?
“Fún àwọn tí kìí rántí nkan dáadáa, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn owó kiaramabani àwọn ènìyàn ní a bá nilẹ nígbà tí Buhari di Ààrẹ ní ọdún 2015.

Gbogbo irú àwọn owó yìí ni a fòpin sí láti bíi oṣù karùn-ún, ọdún 2023 àti ti ajílẹ̀ tí wọ́n ń san ní ọdọọdún tí owó rẹ̀ tó ọgọ́ta sí ọgọ́rùn-ún biliọnu náírà (ìyẹn jẹ́ triliọnu náírà ní bíi ọdún mẹwa). Èyí kìí se irọ́. Owó gọbọyi ni èyí nínú owó isuna ìjọba Àpapọ̀ ní ọdún kọ̀ọ̀kan.”

Ǹjẹ́ ìjọba Buhari yọ owó kiaramabani àwọn ènìyàn fun díṣù gẹ́gẹ́bí Shehu ṣe wí?
Ohun tí ayẹwo wa fi yé wa ni yìí.

Advertisement

AYẸWO

Ní ogunjọ, oṣù kẹfà, ọdún 2023, ijoba Ọbásanjọ́, Ààrẹ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀rí fi owó kún iye tí wọ́n ń tà àwọn nkan tí à ń rí lára epo rọ̀bì (epo pẹntiroolu).

Eléyìí ni ó jẹ́ kí owó lita epo pẹntiroolu kan di náírà mejidinlogoji láti náírà mẹrinlelogun. Eléyìí ni ìbẹ̀rẹ̀ iyọwọkuro ìjọba lórí owó epo pẹntiroolu.

Amọsa, ìfitónilétí Ọbásanjọ́ yìí fà idarudapọ nígbà tí ó se ìjọba ẹkeji.

Advertisement

Ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ (Nigeria Labor Congress-NLC) pe àwọn òṣìṣẹ́ síta káàkiri ilẹ̀ Nàìjíríà láti yan iṣẹ́ lódì. Ẹgbẹ́ tí ó ń rí sí owó ṣíṣe (Trade Union Congress-TUC) àti àwọn tí ó ń jà fún ẹ̀tọ́ àwọn ènìyàn àti àwọn miran sì lọ́wọ́ síi.

Atẹjade kan ní oṣù kẹsàn-án, ọdún 2013 mẹ́nuba àwọn owó kiaramabani àwọn ènìyàn fún díṣù tí Ọbásanjọ́ yọ.

Atẹjade náà ni wọ́n pe àkòrí rẹ̀ ní ‘Epo tí ó ní ìwà ọ̀daràn tí ilẹ̀ Nàìjíríà: Àjọṣepọ̀ àgbáyé láti dín epo rọbi jiji kú. Wíwa epo ni agbegbe tí a mọ̀ sí Niger Delta ní ọ̀nà tí kò yẹ bẹ̀rẹ̀ sí ní wáyé ní ọdún 2009 nígbà tí wọ́n yọ owó kiaramabani àwọn ènìyàn fún díṣù kí Ọbásanjọ́ tó ṣe ìjọba.

“Láti inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nkan tí a rí kà, Niger Delta jẹ́ ibi tí wíwa epo ní ọ̀nà tí kò yẹ ti ń gbẹrẹgẹjigẹ láti ọdún 2009 tàbí ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2010. Lára àwọn ìdí tí ó fàá ni òfin tí kò munadoko tí a ṣe lẹ́hìn ìgbà tí a ṣe ètò ẹmabankanjẹmọ, yíyọ owó kiaramabani àwọn ènìyàn fún díṣù nígbà ìjọba Ọbásanjọ́ àti lílò tí àwọn ènìyàn ń lo epo síi.”

Advertisement

Atẹjade míràn tí ó jáde ní oṣù karùn-ún, ọdún 2023 láti ọwọ́ PricewaterhouseCoopers (PwC) sọ wí pé wọ́n yọ owó kiaramabani àwọn ènìyàn fún díṣù ní ọdún 2003.

Atẹjade yìí sọ wí pé fifikun owó àwọn nkan kí ara má bàa ni àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ ní 1970s, ó sì di ara ètò ìjọba ní ọdún 1977 lẹ́hìn ìgbà tí a ṣe òfin láti fún àwọn ènìyàn ní ààyè láti ta iye tí wọn bá fẹ́ ta nkan. Òfin yìí gba àwọn ènìyàn láyé láti tá epo ní iye tí wọn bá fẹ́.

Advertisement

“Ọdún mẹ́tàlá lẹhin ìgbà tí òfin fún àwọn ènìyàn láyé láti ta díṣù ní iye tí wọ́n bá fẹ́, wọ́n yọ owó kiaramabani àwọn ènìyàn fún kẹrosini ní ọdún 2016,”atẹjade láti ọwọ́ PwC ni ó wí báyìí.

Nígbà tí ó ń sọ ọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí, Jide Pratt, ẹni tí ó ń mojuto ilé-iṣẹ́ tí a mọ̀ sí Cotevis Energy ṣàlàyé pé, botilẹpe Buhari ti yọ owó kiaramabani àwọn ènìyàn ti kẹrosini, wọ́n ti yọ ti díṣù láti ọdún 2003.

Advertisement

“Wọ́n ti yọ ìyẹn láti ọdún 2003. Wọ́n ti ń ronú nípa rẹ̀ láti ọdún 2000. Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ni pé wọ́n ń ṣe àyípadà nípa owó epo pẹntiroolu, díṣù àti kẹrosini).”

Amọsa, ó sọ pé iye tí wọ́n fi lé owó díṣù wáyé láti lè jẹ́ kí àwọn ènìyàn máa táà ju iye tí òfin fi ọwọ́ sì.

Advertisement

“Ní ọdún 2003, àdéhùn wá pé kí wọ́n yọ owó kiaramabani àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ń kùn iye tí owó díṣù bá dé, èyí tí ó túmọ̀ sí pé kí àwọn ènìyàn máa ra díṣù ní iye tí wọ́n ní láti ra,” Pratt ni ó sọ báyìí.

“Ní ọdún 2000, ifasẹyin dé bá àdéhùn yìí nitoripe àwọn ọkọ ilẹ̀ lo díṣù láti kò ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun ọ̀gbìn wọlé.

Eléyìí túmọ̀ sí pé tí wọ́n bá yọọ, owó àwọn nkan lílo àti àwọn iṣẹ́ yóò lọ sókè. Ní ọdún 2003, wọ́n yọọ.”

BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ

Ọ̀rọ̀ tí Shehu sọ pé ìjọba Buhari ni ó yọ owó kiaramabani àwọn ènìyàn fún díṣù kìí se òótọ́. Wọn tí yọọ láti ọdún 2003 nígbà ìjọba Ọbásanjọ́.

Click on the link below to join TheCable Channel on WhatsApp for your Breaking News, Business Analysis, Politics, Fact Check, Sports and Entertainment News!

Tags

0 Comments

No Comments Yet!

There are no comments at the moment, do you want to add one?

Write a comment

Write a Comment

error: Content is protected from copying.