Saturday, April 27, 2024
MARKET UPDATE
Advertisement Topt

TheCable

Advertisement lead

Kì í ṣe òótọ́ ni ọ̀rọ̀ tí Bello el-Rufai sọ pé Hadiza Balarabe ni obìnrin àkọ́kọ́ tí ó jẹ igbá-kejì gómìnà ní Nàìjíríà

Kì í ṣe òótọ́ ni ọ̀rọ̀ tí Bello el-Rufai sọ pé Hadiza Balarabe ni obìnrin àkọ́kọ́ tí ó jẹ igbá-kejì gómìnà ní Nàìjíríà
March 23
14:38 2024

Bello el-Rufai, ọmọ ilé ìgbìmọ̀ asofin tí ó ń sojú Kaduna north federal constituency, sọ pé Hadiza Balarabe ni obìnrin àkọ́kọ́ tí ó jẹ igbá-kejì gómìnà ní Nàìjíríà.

Asofin náà sọ̀rọ̀ yìí lórí ohun igbohunsafẹfẹ ìgbàlódé (podcast) tí Seun Okinbaloye ṣe.

Igbohunsafẹfẹ yìí ní àwọn tí wọ́n tẹlee bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún. Àwọn tí ó wòó tó bíi ẹgbẹ̀rún ni ọ̀nà aadọrun ó lé ní márùn-ún ó dín ní ọgọ́ta àti igba. Àwọn ènìyàn mejileniẹgbẹta ni ó sọ ọ̀rọ̀ nípa ẹ. Ẹgbẹ̀rún mẹta ó dín ní ọgọ́rùn-ún ènìyàn ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ náà.

Àwòrán arákùnrin náà, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ Násírì el-Rufai, gómìnà Ìpínlẹ̀ Kaduna tẹ́lẹ̀ri ni ó wà ní ìsàlẹ̀ yìí.

Advertisement

Ní ọdún 2018, Nasir el-Rufai Balarabe gẹ́gẹ́bí igbá-kejì rẹ̀ fún ìdíje ipò gómìnà ní Ìpínlẹ̀ Kaduna.

Ó ní pé òhun mú Balarabe nítorí pé Barnabas Bantex, igbá-kejì el-Rufai nígbà náà sọ fún òhun pé òhun (Bantex) fẹ́ díje fún ipò asofin ní ilé ìgbìmọ̀ asofin àgbà.

Kí wọ́n tó múu bíi igbá-kejì, Balarabe jẹ́ akọ̀wé àgbà fún ẹ̀ka ìjọba tí a mọ̀ sí Kaduna State Primary Healthcare Development Agency.

Advertisement

ÀYẸ̀WÒ

Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí bàbá rẹ̀ gbé ṣe ni Kaduna, Bello sọ pé bàbá òhun pẹ̀lú àtilẹyin Balarabe tún àwọn ilé-ìwòsàn igba àti marun-leniaadọta ṣe ní Kaduna.

“Lára àwọn ohun tí bàbá mi ṣe pẹ̀lú igbá-kejì rẹ̀ ni pé Dókítà Hadiza (Balarabe), ẹni tí ó jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́ tí ó jẹ igbá-kejì gómìnà ní Nàìjíríà ni pé ó tún àwọn ilé-ìwòsàn ṣe ní Kaduna,”Bello ni ó wí báyìí.

Àmọ́sá, àyẹ̀wò tí TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára ṣe fi hàn pé láti     ìgbà tí Nàìjíríà tí padà sí ìjọba tiwantiwa ní ọdún 1999, Nàìjíríà tí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin tí wọ́n jẹ igbá-kejì àwọn gómìnà ní oríṣiríṣi àwọn Ìpínlẹ̀.

Advertisement

ÀWỌN OBÌNRIN TÍ WỌ́N JẸ IGBÁ-KEJÌ GÓMÌNÀ NÍ NÀÌJÍRÍÀ

Ìpínlẹ̀ Èkó ni ó kọ́kọ́ yan obìnrin gẹ́gẹ́bí igbá-kejì gómìnà. Ní ọdún 1992, nígbà ìjọba alágbádá tí kò pẹ̀, Michael Otedola di gómìnà ní abẹ́ asia òṣèlú National Republican Convention (NRC). Arábìnrin Sinatu Ojikutu ni igbá-kejì rẹ̀.

Ojikutu wà ní ipò yìí títí di ọdún 1993 tí àwọn ológun fi gba ìjọba.

Ní ọdún 1999, Nàìjíríà padà sí ìjọba tiwantiwa. Bola Tinubu jaweolubori, ó sì di gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó ní abẹ́ asia òṣèlú the Alliance for Democracy (AD). Ó sì yan arábìnrin Kofoworọla Akerele-Bucknor gẹ́gẹ́bí igbá-kejì rẹ̀.

Advertisement

Láti ìgbà yìí, àwọn obìnrin bíi Adebisi Sosan, Adejoke Orelope-Adefulire àti Oluranti Adebule di igbá-kejì àwọn gomina Èkó láàárín ọdún 2007 sí 2019.

Ayo Fayose, gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkìtì tẹ́lẹ̀rí yan arábìnrin Abiodun Olujimi gẹ́gẹ́bí igbá-kejì gómìnà àkọ́kọ́ ní ìpínlẹ̀ Èkìtì láti oṣù kẹsàn-án, ọdún 2005 sí 2006.

Advertisement

Funmilayo Olayinka jẹ igbá-kejì gómìnà Kayode Fayemi, láti ọdún 2010 sí 2013 kí ó tó kú. Modupe Adelabu di igbá-kejì gómìnà ní Èkìtì ní oṣù Karùn-ún, ọdún 2013.

Ní ìpínlẹ̀ Ogun, Salimat Badru ṣe igbá-kejì gómìnà Gbenga Daniel láti ọdún 2003 sí ọdún 2011. Yetunde Onanuga jẹ igbá-kejì gómìnà ní ìpínlẹ̀ Ogun láti ọdún 2015 sí ọdún 2019.

Advertisement

Ní ìpínlẹ̀ Osun, Olusola Obada jẹ igbá-kejì gómìnà Olagunsoye Oyinlọla, láti ọdún 2003 sí 2010. Titilayo Laoye-Tomori jẹ igbá-kejì gómìnà ní ìpínlẹ̀ yìí láti ọdún 2010 sí 2018.

Pauline Tallen di igbá-kejì gómìnà Ìpínlẹ̀ Plateau ní ọdún 2007. Ó sì jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ jẹ igbá-kejì gómìnà ní àríwá Nàìjíríà. Ipalibo Banigo jẹ igbá-kejì gómìnà Nyesom Wike, ní ìpínlẹ̀ Rivers, láti ọdún 2015 sí 2023.

Advertisement

Cecilia Ezeilo jẹ igbá-kejì gómìnà Ifeanyi Ugwuanyi, ní ìpínlẹ̀ Enugu ní ọdún 2015.

Noimot Salako-Oyedele ni igbá-kejì gómìnà Dapo Abiodun, ní ìpínlẹ̀ Ogun, ní ọdún 2019, ọdún kan náà tí Balarabe di obìnrin àkọ́kọ́ tí ó jẹ igbá-kejì gómìnà ní ìpínlẹ̀ Kaduna.

Ní ọdún 2022, Balarabe di igbá-kejì gómìnà Uba Sani. Ní oṣù kẹta, ọdún 2023, wọ́n tún yan Balarabe ní ìgbà kejì gẹ́gẹ́bí igbá-kejì gómìnà ní Kaduna.

BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ

Irọ́ ni ọ̀rọ̀ tí Bello el-Rufai sọ yìí.

Sinatu Ojikutu ni obìnrin àkọ́kọ́ tí ó jẹ igbá-kejì gómìnà ní Nàìjíríà.

Click on the link below to join TheCable Channel on WhatsApp for your Breaking News, Business Analysis, Politics, Fact Check, Sports and Entertainment News!

Tags

0 Comments

No Comments Yet!

There are no comments at the moment, do you want to add one?

Write a comment

Write a Comment

error: Content is protected from copying.