MARKET UPDATE
Advertisement Topt

TheCable

Fídíò àwọn ènìyàn tí wọ́n ń fi ẹhonu hàn ní ààfin Emir Ilorin ti pẹ́

Fídíò àwọn ènìyàn tí wọ́n ń fi ẹhonu hàn ní ààfin Emir Ilorin ti pẹ́
February 25
12:07 2024

Ní ọjọ́ Sátidé, fídíò kan tí ó ní àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ẹhonu hàn ní ààfin Emir ti Ilorin ní Ìpínlẹ̀ Kwara ni àwọn ènìyàn ti ń pín kiri ní orí ohun ìgbàlódé ìbáraẹnise (social media).

Nínú fídíò náà, àwọn tí wọ́n ń fi ẹhonu hàn yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọ́n tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ ni wọ́n ń pariwo tí wọ́n sì ń sọ pé “ebi ń pa ìlú (the city is hungry).”

Kíákíá ni àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní pín fídíò yìí, tí àwọn ènìyàn kan sì ń sọ pé ifiẹhonu hàn náà ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ Sátidé àti pé ọ̀wọ́n gógó àwọn ǹkan pàápàá oúnjẹ ló fàá.

Ọ̀wọ́n gógó àti àìsíifọkanbalẹ tí ń yọ àwọn ènìyàn lẹ́nu láti ìgbà pípẹ́ ní Nàìjíríà. Eléyìí tí fa kí àwọn ènìyàn fi ẹhonu hàn ní àwọn ibi kan ní Nàìjíríà.

Advertisement

Ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kejì, àwọn ará Minna, olú ìlú Ìpínlẹ̀ Niger, dí àwọn ọ̀nà ní agbègbè tí wọ́n ń pè ní Kpakungu láti fi ẹhonu wọn hàn lórí ìnira tí ọ̀wọ́n gógó àwọn nkan fà.

Ní ọjọ́ díẹ̀ lẹ́hìn èyí, àwọn ará ìjọba ìbílẹ̀ Suleja ni ìpínlẹ̀ náà ya sí títì láti fi ẹhonu wọn hàn lórí bí àwọn ǹkan ṣe le koko.

Ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù kejì, àwọn obìnrin tí wọ́n ń ta ǹkan ní ọjà ní ìlú Èkó fi ẹhonu wọn hàn lórí ọ̀wọ́n gógó àwọn ǹkan.

Advertisement

Àwọn ènìyàn náà gbé àwọn ǹkan tí wọ́n kọ àwọn kan bíi “Baba Tinubu, ebi ń pa àwọn ọmọ Nàìjíríà” àti “Tinubu, wá gbà wá” sí.

ṢÉ ÀÌPẸ́ NI ẸHONU YÌÍ?

Lẹ́hìn tí TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára, ṣe àyẹ̀wò fídíò yìí tí a sì fi wé àwọn àwòrán tí ó wà ní ààfin Emir yìí, a ríi pé ibi tí ó wà nínú fídíò náà jẹ́ ààfin Emir náà.

Lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwádìí lórí àwọn ohun ìbáraẹnise, TheCable tún ríi pé ìkanṣoṣo  nínú àwọn fídíò tí wọ́n ní kò tíì pẹ́ ni àwọn ènìyàn ń pín ní orí ayélujára, eleyi ti o jẹ́ kí ó yé wa pé èyí lè sini ní ọ̀nà.

Advertisement

Olumulo kan tí a mọ̀ sí @omoelerinjare lórí ohun ìbáraẹnise alámì krọọsi (X, tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀rí) kọ ǹkan tí ó ní “Ìròyìn tí ó gbóná fẹlifẹli: Ifiẹhonuhan gidi ń lọ lọ́wọ́ ní ààfin Emir Ilorin ní Ìpínlẹ̀ Kwara! ‘Ebi ń pa wá. Ebi ń pa Ìpínlẹ̀ yìí.”

Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà irínwó ó dín ní ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ogójì ni wọ́n rí atẹjade náà. Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún méjì ni ó pín ín lórí àwọn ohun ìbáraẹnise.

Advertisement

Lẹ́hìn ìgbà tí TheCable ṣe àyẹ̀wò síi lórí ayélujára, a ríi pé àwọn ènìyàn ti pín fídíò yìí ní orí ohun ìgbàlódé ìbáraẹnise ní ọdún 2021.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ ìsinmi, Ibrahim Sulu-Gambari, Emir tí ìlú Ilorin sọ pé fídíò yìí kì í ṣe fídíò isinyi. Kò sí ní ohunkohun ṣe pẹ̀lú ọ̀wọ́n gógó àwọn ǹkan tí ó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́.

“Wọ́n ti pe àkíyèsí wa sí fídíò kan tí àwọn ènìyàn ń pín kiri ní orí ohun ìgbàlódé ìbáraẹnise níbi tí àwọn ènìyàn tí ń pariwo tí wọ́n sì ń banújẹ́ lórí ìnira tí ọ̀wọ́n gógó àwọn ǹkan fà ní iwájú ààfin Emir Ilorin,” báyìí ni atẹjade yìí ṣe wí.

“A fẹ́ sọ̀rọ̀ laifiikanpemeji pé fídíò tí àwọn ènìyàn ń sọ yìí jẹ́ ara àwọn ǹkan tí àwọn ènìyàn ṣe nígbà tí ètò ìdìbò gboogbogbo ń bọ̀ lọ́nà ní 2019.

“Fídíò yìí kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú bí Nàìjíríà ṣe le koko lọ́wọ́. Ohun tí a mọ̀ ni wí pé Emir tí ìlú Ilorin, ẹni tí ó jẹ́ alága àjọ àwọn ọba, Ibrahim Sulu-Gambari náà fi ẹhonu hàn, wọ́n sì sọ pé kí àwọn ìjọba jẹ́ kí àlàáfíà àti ìgbé ayé tí ó dára wà.”

BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ

Fídíò tí ó ṣe àfihàn àwọn ènìyàn ní ibi tí àwọn ènìyàn ti ń fi ẹhonu hàn ní ààfin Emir Ilorin ní ọjọ́ Sátidé kì í ṣe ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ ní àìpẹ́.

 

 

Click on the link below to join TheCable Channel on WhatsApp for your Breaking News, Business Analysis, Politics, Fact Check, Sports and Entertainment News!

Tags

0 Comments

No Comments Yet!

There are no comments at the moment, do you want to add one?

Write a comment

Write a Comment

error: Content is protected from copying.