MARKET UPDATE
Advertisement Topt

TheCable

Fídíò tí àwọn ènìyàn pín tí ó ṣe àfihàn ilé olókè tó ga gan-an kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìṣẹlẹ (earthquake) tí ó ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Taiwan

Fídíò tí àwọn ènìyàn pín tí ó ṣe àfihàn ilé olókè tó ga gan-an kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìṣẹlẹ (earthquake) tí ó ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Taiwan
April 15
09:48 2024

Àwọn ènìyàn kan ti sọ pé Fídíò kan tí ó ṣe àfihàn àwọn ilé tó ga gan-an ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ìṣẹlẹ tó kọlu orílẹ̀-èdè Taiwan.

Nínú fídíò yìí, àwọn ilé olókè gogoro ń wó lulẹ̀. Àwọn tí ó ń gbé ní agbègbè ìṣẹ̀lẹ̀ yìí fi igbe ta. 

Àwọn ènìyàn ti wo/rí Fídíò tí kò tó idamẹrin ìṣẹ́jú kan yìí tí ẹni kan fi sí orí X (ohun ìgbàlódé tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀) ní ọna ẹgbẹ̀rún marun-leniaadọta. Wọ́n pín ín ní ọ̀nà ọgbọ́n, wọn fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí nígbà mẹtadinlaadọọrin. Wọ́n sì fi pamọ́ láti lè kàá nígbà mìíràn ní ìgbà mẹtalelọgbọn. 

“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé ni wọn ti wó lulẹ̀ lẹ́hìn ìgbà tí ìṣẹlẹ yìí ṣẹlẹ̀,” @patrickhsu0906, ẹni kan tí ó ń lo X ló fi ọ̀rọ̀ yìí ṣe àkòrí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Advertisement

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn mìíràn tí wọn ń lo X ni wọn pín fídíò yìí. Wọn sì sọ pé ti ìṣẹlẹ orílẹ̀-èdè Taiwan ni.

“ÌṢẸLẸ TAIWAN NÍ ARIGBUNGBUN ÌLÀ-OÒRÙN ÉṢÍÀ (ASIA): Ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó bani nínú jẹ́ ni a ti rí àwọn ilé olókè gogoro tí wọ́n ń wó lulẹ̀. 

Ìṣẹlẹ yìí, èyí tí ó ba àwọn ilé jẹ ni ìṣẹlẹ tí ó pọ̀ jù ní ọdún marunlelogun sí ìgbà yìí. Ó sì kan àwọn ènìyàn lára ní àwọn ibì kan ní orílẹ̀-èdè China, Philippines àti Japan. 

Advertisement

“Taipei, Taiwan, ìṣẹlẹ ṣẹlẹ̀ nibẹ, èyí tí ó kó jìnnìjìnnì bá àwọn ènìyàn, tí ó sì kọlu ìlà-oòrùn orílẹ̀-èdè Taiwan ní àárọ̀ ọjọru  tí ó sì pa ènìyàn mẹsan, tí ó sì pa àwọn ènìyàn bíi ẹẹdẹgbẹrun àti mẹtalelọgọta lára. Báyìí ni àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ iná (Fire Department) ní Taiwan ṣe wi,” báyìí ni ẹlòmíràn kan tí ó ń lo X, tí a mọ̀ sí @ZubairSpanish ṣe wí nínú ọ̀rọ̀ tí ó fi sí orí X. 

ÌṢẸLẸ TÓ ṢẸLẸ̀ NÍ TAIWAN 

Ní ọjọru, ìṣẹlẹ kan kọlu Taiwan, ó sì wó àwọn ilé. Ènìyàn mẹsan ló kú. Àwọn ènìyàn tí wọn ju ẹgbẹ̀rún kan lọ ló fi ara pa. 

Àwon kan tí a mọ̀ sí Taiwan’s Central Weather Administration (CWA) sọ pé ilẹ̀ jíjìn kan ní Philippines ló fà ìṣẹlẹ náà.

Advertisement

Bíótilẹ̀jẹ́pé ìṣẹlẹ kò fi bẹ́ẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ ní Taiwan, àwọn ènìyàn ní ti ọjọru yìí ló pọ̀ jù ní ọdún marunlelogun sí ìgbà yìí. 

Ìṣẹlẹ tí kò tó eléyìí tí ṣẹlẹ̀ ní ọdún 1999, èyí tí ó fa ikú fún àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún méjì àti irínwó, tí ó sì pa àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún ní ọna ọgọ́rùn-ún lára

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilé ló bà jẹ́. Taiwan jẹ́ orílẹ̀-èdè tí ìṣẹlẹ lè kọlu.

ÀYẸ̀WÒ 

Advertisement

TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára ṣe ayẹwo ọ̀rọ̀ yìí lórí InVid, ibi tí a ti máa ń ṣe àyẹ̀wò fídíò. A ríi pé fídíò yìí ti wà lórí orí ayélujára láti ọjọ́ kẹtadinlọgbọn, oṣù kẹjọ, ọdún 2021 lórí ìwé ìròyìn kan tí a mọ̀ sí Yunan information platform, ibì kan tí wọn ti máa ń gbé ìròyìn jáde. 

Gẹ́gẹ́bí ibi igberoyin jáde yìí ṣe wí, ilé olókè gogoro mẹẹdogun ni àwọn tí wọ́n ń rí sí ọ̀rọ̀ ilé wó lulẹ̀ ní Yunnan, ní China. 

Advertisement

Wọn wó àwọn ilé yìí nítorí pé wọ́n kò bá ìlànà tí ìjọba fọwọ́ sí lọ. 

Ìwé ìròyìn kan tí a mọ̀ sí USA Today náà tún fi fídíò náà sórí YouTube, ibi tí àwọn ènìyàn máa ń fi àwòrán tàbí fídíò sì kí àwọn ènìyàn lè wòó.

Advertisement

BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ 

Fídíò tí ó ṣe àfihàn àwọn ilé gogoro tí wọn ń wó lulẹ̀ kìí ṣe ti ìṣẹlẹ tí ó ṣẹlẹ̀ ní Taiwan. 

Advertisement

Fídíò àwọn ilé tí àwọn tí ó n ṣàkóso ọ̀rọ̀ ilé wò lulẹ̀ ni, ní ọdún 2021, kí àwọn ilé náà má baa fa ikú tàbí pa àwọn ènìyàn lára. 

Click on the link below to join TheCable Channel on WhatsApp for your Breaking News, Business Analysis, Politics, Fact Check, Sports and Entertainment News!

Tags

0 Comments

No Comments Yet!

There are no comments at the moment, do you want to add one?

Write a comment

Write a Comment

error: Content is protected from copying.